Jeremiah 8:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́? Rárá o, ojú kì í tì wọ́n, nítorí pé wọn kò lójútì. Nítorí náà àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú, a óo bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Itiju yio ba wọn nitori nwọn ti ṣe ohun irira, sibẹ nwọn kò tiju, bẹ̃ni õru itiju kò mu wọn, nitorina ni nwọn o ṣe ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu; ni igba ibẹ̀wo wọn, a o si wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń mí oru-ìtìjú. Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú, a ó sì fà wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá ń fi ìyà jẹ wọ́n, ni OLÚWA wí.