Jeremiah 8:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan Ọlọrun bá dáhùn pé, “Kí ló dé tí a fi jókòó jẹ̀kẹ̀tẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á kó ara wa jọ, kí á sá lọ sí àwọn ìlú olódi, kí á sì parun sibẹ; nítorí OLUWA Ọlọrun wa ti fi wá lé ìparun lọ́wọ́, ó ti fún wa ní omi tí ó ní májèlé mu, nítorí pé a ti ṣẹ̀ ẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẽṣe ti awa joko jẹ? ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si jẹ ki a wọ̀ inu ilu olodi, ki a si dakẹ sibẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wa, ti mu wa dakẹ, o si fun wa ni omi orõro lati mu, nitori ti awa ṣẹ̀ si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“È é ṣe tí a fi jòkó ní ibí yìí? A kó ara wa jọ! Jẹ́ kí a sá lọ sí ìlú olódi kí o sì ṣègbé síbẹ̀. Nítorí tí OLÚWA Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé. Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé láti mu, nítorí àwa ti sẹ̀ sí i.