Jeremiah 8:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mi jákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé, “Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni? Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?” OLUWA, ọba wọn dáhùn pé, “Kí ló dé tí wọn ń fi ère wọn mú mi bínú, pẹlu àwọn oriṣa ilẹ̀ àjèjì tí wọn ń bọ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sa wò o, ohùn ẹkún ọmọbinrin enia mi, lati ilẹ jijina wá, Kò ha si Oluwa ni Sioni bi? ọba rẹ̀ kò ha si ninu rẹ̀? ẽṣe ti nwọn fi ere gbigbẹ ati ohun asan àjeji mu mi binu?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fetí sí igbe àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ tó jìn: “OLÚWA kò ha sí ní Síóní bí? Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?” “È é ṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjòjì tí wọn kò ní láárí?”