Jeremiah 8:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo fọ́n wọn dà sílẹ̀ ninu oòrùn, ati lábẹ́ òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ sí, tí wọ́n sì sìn; àwọn ohun tí wọn ń wá kiri, tí wọn ń ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń bọ. A kò ní kó egungun wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní sin wọ́n. Wọn óo dàbí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí ilẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si tẹ́ wọn siwaju õrùn ati òṣupa ati gbogbo ogun ọrun, ti nwọn ti fẹ, ti nwọn si ti sìn, awọn ti nwọn si rìn tọ̀ lẹhin, ti nwọn si wá, ti nwọn si foribalẹ fun: a kì yio kó wọn jọ, bẹ̃li a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan li oju ilẹ-aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dà bí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀.