Jeremiah 8:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo sàn kí àwọn tí ó bá kù ninu ìran burúkú yìí kú ju kí wọ́n wà láàyè lọ, ní ibikíbi tí mo bá lé wọn lọ. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awon iyokù ti o kù ninu idile buburu yi yio yan kikú jù yiyè lọ: ni ibi gbogbo ti nwọn kù si, ti emi ti tì wọn jade si, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni OLÚWA Àwọn ọmọ ogun wí.’