Jeremiah 8:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ló dé tí àwọn eniyan wọnyi fi yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọn ń lọ láì bojúwẹ̀yìn? Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni wọ́n sì wawọ́ mọ́; wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẽṣe ti awọn enia Jerusalemu yi sọ ipadasẹhin di ipẹhinda lailai? nwọn di ẹ̀tan mu ṣinṣin, nwọn kọ̀ lati pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
È é ṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kílódé tí Jérúsálẹ́mù fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà? Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn, wọ́n kọ̀ láti yípadà.