Jeremiah 8:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn, ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere. Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀, kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’ Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú, bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo tẹti lélẹ, mo si gbọ́, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ titọ: kò si ẹnikan ti o ronupiwada buburu rẹ̀ wipe, kili emi ṣe? gbogbo nwọn yipo li ọ̀na wọn, bi akọ-ẹṣin ti nsare gburu sinu ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo ti fetí sílẹ̀ dáradára, wọn kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀, kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.