Jeremiah 8:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀; wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada. Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lõtọ ẹiyẹ àkọ li oju-ọrun mọ̀ akoko rẹ̀, àdaba ati ẹiyẹ lekeleke pẹlu alapandẹ̀dẹ sọ́ igba wiwá wọn; ṣugbọn enia mi kò mọ̀ idajọ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìsípòpadà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Ọlọ́run wọn fẹ́.