Jeremiah 9:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá, sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀, nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá. A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀. Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Fun awọn oke-nla ni emi o gbe ẹkún ati ohùnrere soke, ati ẹkún irora lori papa oko aginju wọnnì, nitoriti nwọn jona, ẹnikan kò le kọja nibẹ, bẹ̃ni a kò gbọ́ ohùn ẹran-ọsin, lati ẹiyẹ oju-ọrun titi de ẹranko ti sa kuro, nwọn ti lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì sunkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè; àti ẹkún ìrora lórí pápá oko ihà wọ̀n-ọn-nì. Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sá lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.