Jeremiah 9:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “N óo sọ Jerusalẹmu di àlàpà ati ibùgbé ajáko. N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú wọn mọ́. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o sọ Jerusalemu di okiti àlapa, ati iho awọn ikõko, emi o si sọ ilu Juda di ahoro, laini olugbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi yóò sì sọ Jérúsálẹ́mù di òkìtì àlàpà àti ìhò àwọn ìkokò. Èmi ó sì sọ ìlú Júdà di ahoro tí ẹníkẹ́ní kò sì ní le è gbé.”