Jeremiah 9:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá, ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹ kiye si i, ki ẹ si pe awọn obinrin ti nṣọfọ, ki nwọn wá; ẹ si ranṣẹ pè awọn obinrin ti o moye, ki nwọn wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí sì ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí: “Ṣáà wò ó nísisìnyìí! Ké sí obìnrin ọlọ́fà nì kí ó wá; sì ránsẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.