Jeremiah 9:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìbá ṣe pé mo ní ilé èrò kan ninu aṣálẹ̀, ǹ bá kó àwọn eniyan mi dà sílẹ̀ níbẹ̀, ǹ bá sì kúrò lọ́dọ̀ wọn; nítorí alágbèrè ni gbogbo wọn, ati àgbájọ àwọn alárèékérekè eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A! emi iba ni buka ero ni iju, ki emi ki o le fi enia mi silẹ, ki nlọ kuro lọdọ wọn! nitori gbogbo nwọn ni panṣaga, ajọ alarekereke enia ni nwọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áà! èmi ìbá ní ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò ní ihà kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀ kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn: nítorí gbogbo wọn jẹ́ pańṣágà àjọ aláìsòótọ́ ènìyàn ni wọ́n.