Jeremiah 9:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ẹni tí ó bá fẹ́ fọ́nnu, ohun tí ó lè máa fi fọ́nnu ni pé òun ní òye ati pé òun mọ̀ pé, èmi OLUWA ni OLUWA tí ń ṣe ẹ̀tọ́, tí sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òdodo hàn lórí ilẹ̀ ayé; nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni mo ní inú dídùn sí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ki ẹnikẹni ti yio ba ma ṣogo, ki o ṣe e ninu eyi pe: on ni oye, on si mọ̀ mi; pe, Emi li Oluwa ti nṣe ãnu ati idajọ ati ododo li aiye: nitori inu mi dùn ninu ohun wọnyi, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé òun ní òye, òun sì mọ̀mí wí pé, Èmi ni OLÚWA tí ń ṣe òtítọ́ ìdájọ́ àti òdodo ní ayé nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” OLÚWA wí.