Jeremiah 9:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
àwọn ará Ijipti, àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Amoni àwọn ará Moabu, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú aṣálẹ̀; tí wọn ń fá apá kan irun orí wọn; nítorí pé bí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò ṣe kọlà abẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli kò kọlà ọkàn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egipti ati Juda ati Edomu, ati awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, pẹlu gbogbo awọn ti ndá òṣu, ti ngbe aginju: nitori alaikọla ni gbogbo orilẹ-ède yi, ṣugbọn gbogbo ile Israeli jẹ alaikọla ọkàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Éjíbítì, Júdà, Édómù, Ámónì, Móábù àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jínjìn réré ní ihà. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Ísírẹ́lì sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”