Jeremiah 9:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹni kẹ́ ọrun ni wọ́n kẹ́ ahọ́n wọn, láti máa fọ́n irọ́ jáde bí ẹni ta ọfà; dípò òtítọ́ irọ́ ní ń gbilẹ̀ ní ilẹ̀ náà. OLUWA ní, “Wọ́n ń tinú ibi bọ́ sinu ibi, wọn kò sì mọ̀ èmi OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fà ahọn wọn bi ọrun fun eke; ṣugbọn nwọn kò ṣe akoso fun otitọ lori ilẹ, nitoripe nwọn ti inu buburu lọ si buburu nwọn kò si mọ̀ mi, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfà láti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òótọ́ ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn, wọn kò sì náání mi, ní OLÚWA wí.