Jeremiah 9:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí olukuluku ṣọ́ra lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, kí ó má sì gbẹ́kẹ̀lé arakunrin rẹ̀ kankan. Nítorí pé ajinnilẹ́sẹ̀ ni gbogbo arakunrin, a-fọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ sì ni gbogbo aládùúgbò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ mã ṣọra, olukuluku nyin lọdọ aladugbo rẹ̀, ki ẹ má si gbẹkẹle arakunrin karakunrin: nitoripe olukuluku arakunrin fi arekereke ṣẹtan patapata, ati olukuluku aladugbo nsọ̀rọ ẹnilẹhin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ; má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ nítorí pé oníkálukú arákùnrin jẹ́ atannijẹ, oníkálukú ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.