Jeremiah 9:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Olukuluku ń tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ń sọ òtítọ́. Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn ní irọ́ pípa; wọ́n dẹ́ṣẹ̀ títí, ó sú wọn, wọn kò sì ronú àtipàwàdà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikini ntàn ẹnikeji rẹ̀ jẹ, nwọn kò si sọ otitọ: nwọn ti kọ́ ahọn wọn lati ṣeke, nwọn si ti ṣe ara wọn lãrẹ lati ṣe aiṣedede.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì sí ẹni tó sọ òótọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀