Job 1:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Iná Ọlọrun wá láti ọ̀run, ó jó àwọn aguntan ati gbogbo darandaran patapata, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ti nsọ li ẹnu; ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: iná nla Ọlọrun ti ọrun bọ́ si ilẹ, o si jó awọn agutan ati awọn iranṣẹ ni ajorun; emi nikanṣoṣo li o salà lati rohin fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lu tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi níkàn ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”