Job 1:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ìjì líle kan fẹ́ la àṣálẹ̀ kọjá, ó fẹ́ lu ilé náà, ó wó, ó sì pa gbogbo wọn, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, ẹfufu nlanla ti iha ijù fẹ wá ikọlu igun mẹrẹrin ile, o si wolù awọn ọdọmọkunrin na, nwọn si kú, emi nikanṣoṣo li o yọ lati rohin fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì kíyèsí i, ẹfúfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọ lu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọdọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.