Job 1:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?” Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si bi Satani wipe: nibo ni iwọ ti wá? nigbana ni Satani da Oluwa lohùn wipe: ni ilọ siwá sẹhin lori ilẹ aiye, ati ni irinkerindo ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì bi Sàtanì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Nígbà náà ní Sàtanì dá OLÚWA lóhùn wí pé, “Ní ìlọ-siwá-sẹ́yìn lórí ilẹ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”