Job 2:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha ati Sofari ará Naama, àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹta, gbọ́ nípa ìyọnu tí ó dé bá Jobu, wọ́n wá láti kí i, ati láti tù ú ninu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ọrẹ Jobu mẹta gburo gbogbo ibi ti o ba a, nwọn wá, olukuluku lati ibujoko rẹ̀ wá; Elifasi, ara Tema, a si Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama: nitoripe nwọn ti dajọ ipade pọ̀ lati ba a ṣọ̀fọ on ati ṣipẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Élífásì, ara Témà àti Bílídádì, ara Ṣúà, àti Sófárì, ará Náámù: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a sọ̀fọ̀ àti láti sìpẹ̀ fún un.