Job 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n rí Jobu ní ọ̀ọ́kán, wọn kò mọ̀ ọ́n mọ́. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n súnmọ́ ọn tí wọ́n mọ̀ pé òun ni, wọ́n bú sẹ́kún, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì ku eruku sórí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si gboju wọn wò li òkere rére, ti nwọn kò si mọ̀ ọ, nwọn gbe ohùn wọn soke, nwọn sọkun: olukuluku si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, nwọn si kù erupẹ si oju ọrun si ara wọn lori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa àṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á.