Job 2:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé. Ó bẹ̀rù OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú, ó dúró ṣinṣin ninu ìwà òtítọ́ rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o dẹ mí sí i láti pa á run láìnídìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun Satani pe, iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ti o si korira ìwa buburu, bẹ̃li o si di ìwa otitọ rẹ̀ mu ṣinṣin, bi iwọ tilẹ ti dẹ mi si i lati run u lainidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì wí fún Sàtánì pé, “Ìwọ ha kíyèsí Jóòbù ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí èkejì rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòótọ́ tí ó sì dúró sinsin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kóríra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run-ún láìnídìí.”