Job 24:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sofari dáhùn pé, “O sọ wí pé, ‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá; ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà, ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O yara lọ bi ẹni loju omi; ifibu ni ipin wọn li aiye, on kò rìn lọ mọ li ọ̀na ọgba-ajara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun; òun kò rìn mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.