Job 32:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo farabalẹ̀ fun yín, ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó lè ko Jobu lójú, kí ó sì fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án, tabi kí ó fún un lésì àwọn àwíjàre rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani mo fiyesi nyin tinutinu, si kiyesi i, kò si ẹnikan ninu nyin ti o le já Jobu li irọ́, tabi ti o lè ida a lohùn ọ̀rọ rẹ̀!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àní mo fíyèsí yín tinútinú; sì kíyèsí i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jóòbù ní irọ́, tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!