Job 34:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn á kú ikú òjijì, ní ọ̀gànjọ́ òru; á mi gbogbo eniyan jìgìjìgì, wọn a sì kú. Ikú á mú àwọn alágbára lọ láì jẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni iṣẹju kan ni nwọn o kú, awọn enia a si di yiyọ lẹnu larin ọganjọ, nwọn a si kọja lọ; a si mu awọn alagbara kuro laifi ọwọ́ ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìṣẹ́jú kán ni wọn ó kú, láàrin ọ̀gànjọ́ àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́, wọn a sì kọjá lọ; A sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.