Job 42:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn arakunrin ati arabinrin Jobu ati àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pada wá bẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n jẹ àsè ní ilé rẹ̀, wọ́n káàánú rẹ̀, wọ́n sì tù ú ninu, nítorí ohun burúkú tí OLUWA ti mú wá sórí rẹ̀, olukuluku wọn fún un ní owó ati òrùka wúrà kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn arabinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o ti ṣe ojulumọ rẹ̀ rí, nwọn mba a jẹun ninu ile rẹ̀, nwọn si ṣe idaro rẹ̀, nwọn si ṣipẹ fun nitori ibí gbogbo ti OLUWA ti mu ba a: olukuluku enia pẹlu si bùn u ni ike owo-kọkan ati olukuluku ni oruka wura eti kọ̃kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nigbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n báa jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì sìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí OLÚWA ti mú bá a: Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owo kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.