Job 42:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ta nìyí tí ń fi ìmọ̀ràn pamọ́ láìní òye? Àwọn ohun tí mo sọ kò yé mi, ìyanu ńlá ni wọ́n jẹ́ fún mi, n kò sì mọ̀ wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tani ẹniti nfi ìgbimọ pamọ laini ìmọ? nitorina ni emi ṣe nsọ eyi ti emi kò mọ̀, ohun ti o ṣe iyanu jọjọ niwaju mi, ti emi kò moye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ làíní ìmọ̀? Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyi tí èmi kò mọ̀, ohun tí ó ṣe ìyànu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.