Job 7:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ló dé tí ẹ kò lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí kí ẹ sì fojú fo àìdára mi? Láìpẹ́ n óo lọ sinu ibojì. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn n kò ní sí mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẽṣe ti iwọ kò si dari irekọja mi jì, ki iwọ ki o si mu aiṣedede mi kuro? njẹ nisisiyi li emi iba sùn ninu erupẹ, iwọ iba si wá mi kiri li owurọ̀, emi ki ba ti si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn, kí ìwọ kí ó sì mú aìṣédéédéé mi kúrò? Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀, ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní owúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”