Joel 1:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Èso àjàrà ti rọ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti ń gbẹ. Igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ ati igi ápù, ati gbogbo àwọn igi eléso ti gbẹ, inú ọmọ eniyan kò sì dùn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ajara gbẹ, igi ọ̀pọtọ́ si rọgbẹ; igi pomegranate, igi ọ̀pẹ pẹlu, ati igi appili, gbogbo igi igbo li o rọ: nitoriti ayọ̀ rọgbẹ kuro lọdọ awọn ọmọ enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pómégánátì, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi ápíílì, gbogbo igi igbó ni o rọ: Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn