Joel 1:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ. Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn, nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ dì ara nyin li amùre, si pohùnrére ẹkún ẹnyin alufa: ẹ hu, ẹnyin iranṣẹ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo oru dùbulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun mi: nitori ti a dá ọrẹ-jijẹ, ati ọrẹ-mimu duro ni ile Ọlọrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùn réré ẹkún ẹyín àlùfáà: ẹ pohùn réré ẹkún, ẹyín ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìrànsẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ jíjẹ àti ọrẹ mímú dúró ní ilé Ọlọ́run un yín.