Joel 2:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, nítorí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ, alágbára ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ ẹ̀rù ni ọjọ́ OLUWA! Ta ló lè faradà á?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ jade niwaju ogun rẹ̀: nitori ibùdo rẹ̀ tobi gidigidi: nitori alagbara li on ti nmu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ; nitori ọjọ Oluwa tobi o si li ẹ̀ru gidigidi; ara tali o le gbà a?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò sì bú rámu ramù jáde níwájú ogun rẹ̀: nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi; nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ; nítorí ọjọ́ OLÚWA tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi; ara ta ni ó lè gbà á?