Joel 2:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ pe gbogbo eniyan jọ, kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́. Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ. Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀, kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kó awọn enia jọ, ẹ yà ijọ si mimọ́, ẹ pè awọn àgba jọ, ẹ kó awọn ọmọde jọ, ati awọn ti nmu ọmú: jẹ ki ọkọ iyàwo jade kuro ni iyẹ̀wu rẹ̀, ati iyàwo kuro ninu iyẹ̀wu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ, ẹ ya ìjọ sí mímọ́; ẹ pe àwọn àgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọdé jọ, àti àwọn tí mú ọmú: jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú iyẹ̀wù rẹ̀. Kí ìyàwó sì kúrò nínù ìyàrá rẹ̀