Joel 2:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ. Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí, má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé, ‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jẹ ki awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, sọkun lãrin iloro ati pẹpẹ, si jẹ ki wọn wi pe, Dá awọn enia rẹ si, Oluwa, má si ṣe fi iní rẹ fun ẹ̀gan, ti awọn keferi yio fi ma jọba lori wọn: ẽṣe ti nwọn o fi wi ninu awọn enia pe, Ọlọrun wọn há da?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ OLÚWA, sọkún láàrin ìlorò àti pẹpẹ, sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí OLÚWA, má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn, ti àwọn aláìkọlà yóò fi má jọba lórí wọn: èéṣe tí wọn yóò fi wí láàárin àwọn ènìyàn pé, ‘Ọlọ́run wọn há da?’ ”