Joel 2:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín, n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan. N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn, n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Òkú wọn yóo máa rùn; n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi o ṣi ogun ariwa nì jinà rére kuro lọdọ nyin, emi o si le e lọ si ilẹ ti o ṣá, ti o si di ahoro, pẹlu oju rẹ̀ si okun ila-õrun, ati ẹhìn rẹ̀ si ipẹkùn okun, õrùn rẹ̀ yio si goke, õrùn buburu rẹ̀ yio si goke, nitoriti o ti ṣe ohun nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín, èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro, pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí òkun ìlà oòrùn, àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀ oòrùn òkun. Oòrùn rẹ̀ yóò sì gòkè, òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.” Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá.