Joel 2:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú igbó, nítorí ewéko gbogbo ni ó tutù, igi gbogbo ti so èso, igi ọ̀pọ̀tọ́ ati ọgbà àjàrà sì ti so jìnwìnnì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ má bẹ̀ru, ẹranko igbẹ: nitori pápa-oko aginju nrú, nitori igi nso eso rẹ̀, igi ọ̀pọtọ ati àjara nso eso ipá wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó, nítorí pápá-oko ihà ń rú, nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ipá wọn.