Joel 2:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni, kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín; nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò, ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín: ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ jẹ ki inu nyin dùn, ẹnyin ọmọ Sioni, ẹ si yọ̀ ninu Oluwa Ọlọrun nyin; nitoriti o ti fi akọrọ̀ ojò fun nyin bi o ti tọ́, on o si mu ki ojò rọ̀ silẹ fun nyin, akọrọ̀ ati arọ̀kuro ojò ni oṣù ikini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Ṣíónì, ẹ sì yọ̀ nínú OLÚWA Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.