Joel 2:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan, àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá, àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, nikẹhìn emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo; ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma ṣotẹlẹ, awọn arugbo nyin yio ma lá alá, awọn ọdọmọkunrin nyin yio ma riran:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Yóò sì ṣe, èmi yóò tú ẹ̀mi mí sí ara ènìyàn gbogbo; àti àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa ṣọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọ́kunrìn yín yóò máa ríran.