Joel 2:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ OLUWA ni a óo gbàlà. Àwọn kan yóo sá àsálà ní òkè Sioni, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, àwọn tí OLUWA pè yóo sì wà lára àwọn tí wọn yóo sá àsálà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ke pè orukọ Oluwa li a o gbàla: nitori li oke Sioni ati ni Jerusalemu ni igbàla yio gbe wà, bi Oluwa ti wi, ati ninu awọn iyokù ti Oluwa yio pè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò sí ṣe ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ OLÚWA ní a ó gbàlà: nítorí ní òkè Ṣíónì àti ní Jérúsálẹ́mù ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí OLÚWA ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí OLÚWA yóò pè.