Joel 2:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìró wọn dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ogun, wọ́n ń bẹ́ lórí àwọn òkè ńlá. Ìró wọn dàbí ìró iná tí ń jó pápá, bí ìgbà tí àwọn alágbára ọmọ ogun múra fún ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ariwo kẹkẹ́ lori oke ni nwọn o fò, bi ariwo ọwọ́-iná ti o jó koriko gbigbẹ, bi alagbara enia ti a tẹ́ ni itẹ́gun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́ iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kó jọ fún ogun.