Joel 2:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń sáré bí akọni, wọ́n ń fo ògiri bí ọmọ ogun. Wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ẹnikẹ́ni kò sì yà kúrò ní ọ̀nà tirẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o sare bi awọn alagbara; nwọn o gùn odi bi ọkunrin ologun; olukuluku wọn o si rìn lọ li ọ̀na rẹ̀, nwọn kì yio si bà ọ̀wọ́ wọn jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára; wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun; olúkúlúkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀, wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn.