Joel 3:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA kígbe láti Sioni, ó sọ̀rọ̀ láti Jerusalẹmu; ọ̀run ati ayé mì tìtì, ṣugbọn OLUWA ni ààbò fún àwọn eniyan rẹ̀, òun ni ibi ààbò fún Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa yio si ké ramùramù lati Sioni wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ jade lati Jerusalemu wá; awọn ọrun ati aiye yio si mì: ṣugbọn Oluwa yio ṣe ãbò awọn enia rẹ̀, ati agbara awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò sí ké ramúramú láti Ṣíónì wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jérúsálẹ́mù wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì Ṣùgbọ́n OLÚWA yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.