Joel 3:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Israẹli, o óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ, èmi ni mò ń gbé Sioni, òkè mímọ́ mi. Jerusalẹmu yóo di ìlú mímọ́, àwọn àjèjì kò sì ní ṣẹgun mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li ẹnyin o mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, ti ngbe Sioni oke mimọ́ mi: nigbana ni Jerusalemu yio jẹ mimọ́, awọn alejo kì yio si là a kọja mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ń gbé Ṣíónì òkè mímọ́ mi. Ìgbà náà ni Jérúsálẹ́mù yóò jẹ́ mímọ́; àwọn àlejò kì yóò sì kó o mọ́.