Joel 3:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà náà, àwọn òkè ńlá yóo kún fún èso àjàrà, agbo mààlúù yóo sì pọ̀ lórí àwọn òkè kéékèèké. Gbogbo àwọn odò Juda yóo kún fún omi. Odò kan yóo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn láti ilé OLUWA, yóo sì bomi rin àfonífojì Ṣitimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, awọn oke-nla yio ma kán ọti-waini titún silẹ, awọn oke kékèké yio ma ṣàn fun warà, ati gbogbo odò Juda yio ma ṣan fun omi, orisun kan yio si jade lati inu ile Oluwa wá, yio si rin afonifojì Ṣittimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè-ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀, àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa ṣàn fún wàrà; gbogbo odò Júdà tí ó gbẹ́ yóò máa ṣàn fún omi. Oríṣun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ile OLÚWA wá, yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣítímù.