Joel 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
n óo kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí àfonífojì Jehoṣafati, n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀; nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli, àwọn eniyan mi. Wọ́n ti fọ́n wọn káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifojì Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibẹ̀ nitori awọn enia mi, ati nitori Israeli iní mi, ti nwọn ti fọ́n ka sãrin awọn orilẹ̀-ede, nwọn si ti pín ilẹ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀ èdè jọ pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jéhóṣáfátì. Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi, àti nítorí Ísírẹ́lì ìní mi, tí wọ́n fọ́nká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.