John 1:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo Òun ọmọ bíbí kan ṣoṣo, àní Àyànfẹ́ rẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.