John 1:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí sì ni ẹ̀rí Jòhánù, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì láti Jérúsálẹ́mù wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe.