John 1:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Ẹ ká lọ, ẹ óo sì rí i.” Wọ́n bá bá a lọ, wọ́n rí ibi tí ó ń gbé. Wọ́n dúró lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí ó ti tó bí nǹkan agogo mẹrin ìrọ̀lẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O wi fun wọn pe, Ẹ wá wò o. Nwọn si wá, nwọn si ri ibi ti o ngbé, nwọn si ba a joko ni ijọ na: nitoriti o jẹ ìwọn wakati kẹwa ọjọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.” Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.