John 10:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere ni a fi fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, nítorí ọ̀rọ̀ àfojúdi tí o sọ sí Ọlọrun ni; nítorí pé ìwọ tí ó jẹ́ eniyan sọ ara rẹ di Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Ju si da a lohùn, wipe, Awa kò sọ ọ li okuta nitori iṣẹ rere, ṣugbọn nitori ọrọ-odi: ati nitori iwọ ti iṣe enia nfi ara rẹ ṣe Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-ọ̀dì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ ṣe Ọlọ́run.”