John 11:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn Juu tí ó wà ninu ilé pẹlu Maria, tí wọn ń tù ú ninu, rí i pé ó sáré dìde, ó jáde, àwọn náà tẹ̀lé e, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti lọ sunkún ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn Ju ti o wà lọdọ rẹ̀ ninu ile, ti nwọn ntù u ninu, nigbati nwọn ri ti Maria dide kánkan, ti o si jade, nwọn tẹ̀le e, nwọn ṣebi o nlọ si ibojì lọ isọkun nibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Màríà tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀.